ÈTÒ ÌYÍPADÀ OJÚ-ỌJỌ́ FÚN AGBÈGBÈ RC NÍ ÈDÈ YORÙBÁ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwadi ti fi hàn pé tí a kò bá fẹ́ kí oríṣiríṣi akọlu kí ó ṣẹlẹ̀, a gbọ́ dó dẹ́kun bí ìwọ̀n ìgbóná gbogbo àgbáyé tí ń go ké sí títí di ọdún 2030. Ìwọ̀n ìgbóná tí ó pò jù yíò ṣe jà bá tí ó pò sí àyíká, ètò ogbin, gbogbo ènìyàn àti èmí. Láti máa jẹ kí oríṣiríṣi akọlu yí kí o ṣẹlẹ̀ agbodo mú ra lati dín itujade gaasi si afẹ́fẹ́ ku.

Bó ti lè jẹ pé ètò ọ̀rọ̀ ajé wa ń fi gbogbo ona wá èrè pẹ̀lú aibikita akọlu tí ó lè ṣẹlẹ̀ si àyíká , a gbọ́dọ̀ gba àyíká wá nípa fífi òpin sí àwọn ohun ti o n bá àyíká jẹ. A ní ló láti yipada kí a sì fi òpin sí ìnilára ati ilokulo ti wọn fi idire mú lè.

Lati ṣe èyí, a ní ló ifowosowopo gbogbo àgbáyé lati dín aidogba ku ati ọrọ ajé tí yio mú ìgbé ayé rere bá gbogbo ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àgbáyé. Eyi ni lo ìṣọ̀kan àti ìfọkànsìn gbogbo ènìyàn láì fi ẹnikan silẹ. Pẹ̀lú olórí tí yóò kó gbogbo ènìyàn yálà òṣìṣẹ́, aláìní, obìnrin àti odo. Awọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ àyípadà ojú-ọjọ́ má ń ṣẹlẹ̀ sí jù ni aláìní atí awọn ti inira pọ fún gidigidi.

wọnwọnyigbọ́dọ̀kópanínuẁíwàọ̀nààbáyọsìàyípadàojúọjọ́àtiewurẹ.Ohuntiabaṣeniọdúnmẹwa sì ibí yí, yóò ni ipa pataki nínú ayé àwọn tí ohùn bó àti nínú ayé gbogbo ohun ẹ̀mí. Èyí jásí wípé a ni ipa pataki láti kó.
Igbese ti a ní ló lati gbé ni wọnyi:

AGBÁRA

A nílò láti ṣe:

  • Yára láti dín wiwa àti lílọ gaasi afẹ́fẹ́ ku nípa gbogbo ètò irinna, isẹ àti bí a se ń lò;

  • Jẹ́ kí itanna jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ fún gbogbo ènìyàn;

  • Dinku lílo agbára sì ipele tí ó jẹ iwọntún-wọnsì;

  • Ṣíṣe àti lẹ́yìn fún agbára isodotun àti pín pín ìmò agbára imọ-ẹ̀rọ àti imọ ìjìnlẹ̀ káríayé;

  • Rí rọ́pò ẹ̀rọ ìparun pẹ̀lú agbára isodotun, kii ṣe pẹlu epo fosaili.

    DÍDÌ AGBÈGBÈ TI O RỌ́KÚ TI O SI JẸ ALAGBERO

    A nílò láti ṣe:

  • Dáàbò bo omi ilẹ̀ fún ìwúlò gbogbo ayé;

  • Ṣe awọn agbegbe ni agbára- nípa fífún gbogbo ènìyàn, ní pàtàki àwọn olùgbé tí ó ní ipalara (àwọn ènìyàntí ó ní àìlera, ọmọdé, àgbàlagbà, aláìní) nípa pípèsè ohùn tí wọn nílò láti farada ipa iyipada ojú-ọjọ́. (Nkan wọn yi ni, itọju tí ó péye, ẹ̀kọ́, isẹ ti o dára pẹlu owó gidi àti ànfàní, oúnjẹ àti omi tí mọ);

• Ìwúrí àti atileyin fún ìgbé ayé tí ó yàtò ti o dín lílo agbára ku ní pàtàki ju ní orílè èdè àwọn olóró;

• Pípa ri ogun àti lílo owó àwọn ọmọ ológun fún agbára isodotun àti agbára tí ó mọ̀.

ÈTÒ Ọ̀GBÌN, LÍLO ILẸ̀ ÀTI OÚNJẸ

A ní láti ṣe:

• Ṣíṣe ètò ọ̀gbìn tí ó lè dojú kọ iyipada ojú-ọjọ́ (ẹran-ọ̀sìn, isẹ ọ̀gbìn tí kò ní ìpalára fún ènìyàn, ewéko, ilé, igi àti yẹpẹ;

  • Dínkù jíjẹ ẹran-ọ̀sìn àti lílo agbára ní orílẹ̀- èdè ọlọrọ;

  • Dáàbò bo alu mọ ní (òkun, igi, igbó, omi) pẹlu ifowosowopo àwọn olórí agbegbe yí;

  • Dinku fífi oúnjẹ sọ fún.

    ÈTÒ IRINNA

    A ní láti ṣe:

  • Pípèsè eto irinna tí ku wọn ju fún gbogbo ènìyàn pẹlu ọkọ tí ń lò agbára isodotun;

  • Atunto àwùjọ wá kí ó lè rọrùn fún àwọn ènìyàn láti gbé àti ṣe iṣẹ́, kí irinke rìn do ọkọ lè dínkù.

    SISETO TÍ Ó KÚN OJÚ ÒṢÙWỌ̀N

    A ní láti ṣe:

  • Ṣé atileyin fún àwọn orílẹ̀-ede àti ẹ̀yà ènìyàn;

  • Ṣé atileyin fún àwọn olùgbé iwájú àti odo;

  • Sise ifowosowopo tí yóò dẹkùn iyipada ojú-ọjọ́ tí yóò sì mú àwùjọ kúrò nínú ilokulo, ìnilára ati fi fún ohun èmi ni ayé tí ó dára;

• Rii daju pe awọn orilẹ-ede ọlọrọ pese awọn orisun fun awọn ipinnu agbaye si iyipada oju-ọjọ ati pe wọn fun awọn orilẹ-ede miiran ni imọ-ẹrọ ati iranlọwọ owo ti wọn nilo fun awọn ipilẹ ti o yẹ ni agbegbe lati koju rẹ;

• Agbekale eto fun awon eniyan lati din itujade gaasi ku-paapa ni awọn orílè-èdè ọlọro, ibi ti kọọkan eefin gaasi itujade ti ga ju lọ.

ISẸ ṢÍṢE GẸǴ Ẹ́ BÍI OLUBADAMORAN

Gẹ́gẹ́ bí olubadamoran a lè ṣe:
• Ṣe idanimọ ati idasilẹ awọn ipọnju ti o jẹ ki a kọyin si ipo ti awa bayi ati ṣiṣẹ papọ pẹlu gbogbo eniyan lati mọ ọ̀nà àbáyọ -awọn eyi ti o sopọ laarin iyipada oju -ọjọ, inilara, ati ipaeyarun;

• Bi bá awọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nipa iyipada oju-ọjọ- awọn okunfa (pẹlu awọn gbigbasilẹ ipọnju nínú ayé ènìyàn), awọn abajade, iyatọ (iyasọtọ ) ipa lori awọn agbegbe iwaju, ati awọn ọ̀nà àbáyọ -ni ọna ti yoo mú wá gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ati lapapọ;

  • Lílò ati pípín awọn ilana àti oyè RC ni ibigbogbo;

  • Yiyo awọn iṣoro ati awọn ibẹru eyikeyi silẹ ti o le dabaru pẹlu ironu wa ati ṣiṣe ni ọgbọn, pẹlu

    iduroṣinṣin ati igboya, ni awujọ ti o gbooro- awọn iwuwo ti o ṣee ṣe bi iyipada oju -ọjọ ti nlọsiwaju.

    Orúkọ mí ni Adekunle Akinola RC Agbegbe Àkúré,
    Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.


Last modified: 2022-12-16 23:38:27+00